Ibeere: Nigba miiran mo maa n roo pe, N je Eleda tile feran mi. Bi o ba je bee pe Olorun Onife ni, kini eredi re ti iponju ati ikoro fi po to-bee laye yi?
Idahun: Ninu iwe re ti a npe ni Bibeli, Olorun fi han wa gbangba Pe, awon Ese wa lo n fa iponju ati ikoro. Looto ni Olorun fi ife re han si gbogbo araye, gege bi ati lee ka ninu awon ese Bibeli wonyi:
Nitori Olorun fe araye to bee-ge, ti o fi Omo bibi re kanSoSo funni, ki enikeni to ba gba-a-gbo ma ba Segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun. Johannu 3:16
Biotile-wu-kori, oro Olorun je pipe. Bibeli wi pe:
Ona Eniyan buburu, irira ni loju Oluwa; sugbon o fe eni-ti n to Ododo leyin. Owe 15:9
Nitori Olorun mo Ona awon Olododo; Sugbon Ona awon Eniyan Buburu ni yo Segbe. Orin Dafidi 1:6
Ibeere: Sugbon Emi kii Se eniyan buburu. N kii huwa palapala, mo sii n kiyesara to ewe. Ise rere mi tile tewon lopolopo ju buburu ti mo Se lo. Bawo lawon ese Oro wonyi se kan mi?
Idahun: Eni ti o ro pe; Oniwa-pipe julo ni Oun. Ni Olorun n Wo gege bi Ogbo Elese to n lo kankan sorun Apaadi. Bibeli ko wa pe ko si enikan tope to le e fun-ra're lo si Orun rere. Nitori pe gbogbo eniyan lo ti se, ti won sii ti jebi niwaju OLORUN
Gege bi ati koo pe, ko si eni ti nSe Olododo, ko si enikan: ko si eni ti Oye ye, ko si eni ti nwa Olorun. Romu 3:10-11
Okan Eniyan kun fun etan ju ohun gbogbo lo, o sii buru jayi! tani o le moo? Jeremiah 17:9
Ibeere: Bi mo ba je ENIYAN buburu tobee niwaju Olorun, Kini Olorun yoo se simi?
Idahun: Bibeli kowa pe, Ni gbati Opin ba de ba aye yi. awon eniyan buburu yoo gba idajo won lo sinu ina, ti won npe ni Orun apaadi
Nitori pe ina kan ran ninu ibinu mi, yo si jo de ipo-oku ni isale, yo sii run aye pelu asunkun re, yoo si tinabo ipile awon oke Nla. Emi o ko ohun buburu jo le won lori; emi o si lo ofa mi tan si won lara: Ebi yoo mu won gbe,Ooru gbigbona ni a o fi run won, pelu oro Ohun ti nrako ninu erupe. Deuteronomi 32:22-24
Ibeere: O! O! Bawo niyen? Iro ni, orun apaadi O daju, A bi o ro 'pe o daju looto? Bi o ba tile ri bee, n nkan o le buru to yen.
Idahun: Laiseaniani, Orun Apaadi daju, yoo sii buru fun enikeni ti ko ba mo JESU kristi ni OLUWA ati Olugbala re. Iwe Mimo Bibeli ti se Opo Alaye Bi orun Apaadi tiri, ni eyi to Se apejuwe iya ati Oro Ayeraye inuu re to buru julo fun gbogbo eni to ba lo sibe.
'Bi a ba si ri enikeni ti a ko ko Oruko re sinu iwe iye, a soo sinu Adagun ina, Ifihan 20:15
Gege beeni yoo si ri nigbeyin aye; awon angeli yoo jade wa, won o ya awon eniyan buburu kuro ninu awon olooto, won o si so won sinu ina ileru (tabi ina Ajooku) nibe ni ekun ohun ipayinkeke yoo gbe wa. Matteu 13:49-50
Ati fun eyin, ti a n pon loju, isimi pelu wa, nigba ifarahan JESU OlUWA lati orun wa ninu owo ina pelu awon angeli alagbara re, eni ti yoo san esan fun awon ti ko mo Olorun, ti won ko si gba iyinrere Jesu Oluwa gbo: Awon eni ti yoo jiya iparun ainipekun lati iwaju Oluwa wa, ati lati inu ogo agbara re. II Tessallonika 1:7-9
Ibeere: Iyen ma buru o. Kini Eredi ti Olorun fi da Ina Orun Apaadi?
Idahun: Ina Orun Apaadi buru jojo, o si wa looto. nitori pe OLORUN da Eniyan ko le jiyin Ise re niwaju Olorun ni. Idajo Olorun to peye n beere fun gbese Ese wa. Nitori iku ni ere Ese; sugbon ebun ofe Olorun ni iye ti ko nipekun, ninuu JESU OLUWA wa. Iwe Romu 6:23
'Nitori pe gbogbo wa ko le Sai-ma-fi ara han niwaju ite idajo kristi; ki olukuluku ki o le gba n nkan wonni ti o Se ninu ara, gege bi eyi ti o ti Se, i baa Se rere Ibaa Se buburu. II Korinti 5: 10
'Sugbon mo wi fun yin, gbogbo oro were ti eniyan n so, won o jiyin re ni ojo Idajo. Matteu 12:36
Ibeere: Se iyen tumo si pe nigbeyin aye yii, Olorun yoo ji gbogbo wa dide, ko le se idajo, ko le ran awon ero Orun apaadi lo si orun apaadi.
Idahun: Dajudaju, Yoo ri bee gege ayafi bi a ba wa enikan ti yoo faragba iya-ese Olonroro Orun Apaadi ti a da dipo wa, enikan SoSo naa ni Olorun fun ra ra re,to parada wa sinu aye yi gege bii Jesu Olugbala lati wa faragba iya eSe, fun gbogbo eni o ba ni igbagbo ninuu re.
Gbogbo wa ti Sina kirikiri bi Agutan, olukuluku wa tele ona ara re; Oluwa si ti mu aisedeede wa gbogbo pade lara re. Isaiah 53:6
Sugbon a Saa ni Ogbe nitori irekoja wa, a pa a lara nitori aiSedeede wa; ina alaafia wa mbe lara re, ati nipa ina re ni a fi mu wa larada. Isaiah 53:5
'Nitori pe Siwaju ohun gbogbo mo fi eyi ti emi pelu ti gba le yin lowo, bi Kristi ti ku nitori ese wa gege bi iwe Mimo ti wi; Ati pe ati sinku re, ati pe o jinde ni ojo keta gege bi iwe-mimo ti wi. 1 Korinti 15:3-4
Nitori o ti fi Se eSe nito ri wa,eni ti ko mo eSekeSe ri;ki awa lee di ododo Olorun ninuu re. 11 Korinti 5:21
Ibeere: O n so wi pe, bi mo ba ti gbekele Kristi gege bi Oluropo Ese mi, Eni to ti Jiya nitori Ese mi,ewe ko ye ki n tun jaya Orun Apaadi mo?
Idahun: Bee gege lori, bi mo ba ti gba Kristi gbo gege bi Olugbala mi, Nigba naa, n Se ni n o dabi eni to ti duro niwaju ite Idajo Olorun ni. Kristi gege bi Oluropo iya mi ti san gbese Ese mi.
Eni ti o ba gba Omo gbo o ni Iye Ainipekun: eni ti ko ba sii gba omo gbo, ko yoo ri Iye; Sugbon Ibinu Olorun n be lorii re. Johannu 3 : 36
Ibeere: Sugbon kini itumo re pe ki a gbaa gbo? Se bi mo ba ti faramo awon ohun ti Bibeli so nipa Kristi gege bi Olugbala, se mo ti bo lowoo lilo si orun Apaadi niyen?
Idahun: Gbigba Kristi gbo ni Opolopo itumo ninu ju igbagbo taa ni lokan wa si awon ooto Oro inuu Bibeli lo. Itumo eyi ni pe,A gbodo gbe gbogbo ayee wa lee lowo, ati pe Gbogbo Ipa aye wa gbodo maa Se deede pelu Ilana Otito ti a la sile kedere ninu Bibeli. Eyi tumo si pe Ki a yipada kuro ninu Ese wa, ki a sii maa sin Kristi gege bi OLUWA wa.
'Ko si eni ti o lee sin Oluwa meji; nitori yala yoo korira okan yoo si yan ekeji ni iposi. Eyin ko le sin Oluwa pelu Mamooni. Matteu 6:24
Nitori naa e ronu-piwada, ki e sii tun yipada, ki a le pa Ese yin re, ki akoko itura baa le tiwaju Oluwa wa.: Ise awon Aposteli 3:19
Ibeere: O n so wi pe ko si Ona miiran ti ale fi bo lowo ina ijiya Orun Apaadi, bikose nipase JESU? Awon Elesin miiran n ko? Se awon Omo-leyin won yoo lo sOrun Apaadi ni bi?
Idahun: Beeni,o daju. Won ko lee bo lowo ooto yi to so pe, gbogbo wa ni yoo Siro awon Ese wa. Olorun n beere pe ka san gbese awon Ese wa. Kosi Esin to le Se irapada fun Ese awon Omoleyin re, bikose Kristi JESU nikansoso to je Ona to si sile lati ru Ebi-ese wa lo, ko si gbawa la.
'Ko si si Igbala lodo elomiran: nitori ko si oruko miran labe orun ti a fi funni ninu eniyan, nipa eyi ti a le fi gba wa la. Ise Awon Aposteli 4:12
JESU so pe: Emi ni Ona, ati Otito, ati iye: ko si enikeni ti o lee wa sodo Baba, bi ko Se nipase mi. Johannu 14:6
'Bi awa ba jewo ese wa, Olooto ati Olododo ni Oun lati dari ese wa ji wa, ati lati we wa nu kuro ninu aiSododo gbogbo. 1 Johannu 1:9
Ibeere: Ni bayi ara mi o bale rara, Mo ti setan. N o fe lo si orun apaadi, kini mo le Se?
Idahun: O gbodo ranti pe OLORUN nikanSoso lo lee ran O lowo bayi, pelu amoran wi pe ki o jowo ara sile patapata fun Aanu Olorun, nipa wiwo ipo Osi ati ese ti o wa niwaju Olorun. Kigbe soke si Olorun pe ko jowo wa gba okan re la.
Sugbon Agbowo-Ode duro ni okeere, ko tile je gbe Oju re soke orun, sugbon o lu ara re ni ookan-aya, o wi pe, Olorun Saanu fun mi, emi eleSe. Luku 18:13
O si i mu won jade, o ni, Alagba, kini ki emi ki o Se ki n le la? Ise awon Aposteli 16:30-31
Nitori enikeni ti o ba sa pe oruko, Oluwa ni a o gbala. Romu 10:13
Ibeere: Sugbon bawo ni mo Se le gba Kristi gbo, nigba ti o je pe ohun die ni mo mo nipa re ?
Idahun: Si iyanu,Igbala nipa se Jesu Oluwa nikan, ko ni Olorun fun wa, bikose pe o tun se afikun agbara re fun wa,lati le ni igbagbo ninu re.O le gbadura si OLORUN bayi, ki o fun o ni emi i-fi-okan-tan JESU KRISTI gege bi Olugbala re.
Nitori oore-ofe ni ati fi gba yin la nipa igbagbo; ati eyi-i-ni ki i Se ti eyin tikarayin: ebun Olorun ni. Efesu 2:8
OLORUN Sise ni pataki ni-pase BIBELI lati fun wa ni Oye Igbagbo,nitooto, bi o ba Setan lati mu OLORUN ni OLORUN gidi. Ti o ko si fi Oro Igbala okan re fale. O gbodo lo gbogbo anfaani to Si sile fun O bayi lati tetisile ki o si i maa ko Eko Bibeli eyi tii se Oro OLORUN nikansoso.
Ninu iwe Ilewo yi, gbogbo Ese Bibeli to wa nibe lako leyaa leta Italiiki. ka won yekeyeke pelu gbogbo Aya re.
N je nipa gbigbo ni igbagbo ti i wa, ati gbigbo nipa Oro Olorun. Romu 10 : 17
Ibeere: N je Eyi tumo si pe, mo nilati jowo Ohun gbogbo sile fun OLORUN bi?
Idahun: Beeni. OLORUN n fe ki awa si Odo re pelu Irele okan patapata,ki a Kiyesi awon Ona Ese wa,Ona Ainireti wa, ka sii wa gbe gbogbo Okan wa lee.
'Ni Oluwa wi: Sugbon eleyi ni emi yoo wo, ani otoSi ati Onirobinuje Okan,ti o si n wa-riri si Oro mi. Isaiah 66:2b
A feran awon Ese wa nitori pe gbogbo wa je Elese Nitori naa, a gbodo beresi ni gbadura si Olorun ko le funwa ni Emi Ikorira si awon Ese wa gbogbo. Bi a ba n fe Igbala Okan wa looto. Ani lati bere si ni yipada kuro ninu awon Ese wa bi OLORUN ba ti n fun wa ni Okun si. Amo dajudaju pe Ese wa le ran wa lo si Orun Apaadi
Nigba ti Olorun ji JESU omo re dide, o koko ran an si yin lati busi i fun yin, nipa yiyi olululuku yin pada kuro ninu iwa buburu re. Ise awon Aposteli 3:26
Ibeere: N ko le so boya mo ti setan lati Se bee. E funmi ni Akoko die sii, ki n fi rOnu nipa re.
Idahun: O le ma ni Akoko to bi o ti le ro, ati pe, Ile Ola le ma moo ba O laye yi. Gbo ohun ti Olorun so fun Okunrin naa ti o fi Ohun aye se Igbekele re. O lee so fun o bee gege pe: 'Iwo Asiwere ni Oru yi ni a o beere emi re lowo re: n je ti tani n-nkan won-ni yoo ha Se,ti iwo ti pese sile? Luku 12 : 20
Bakanna a Bibeli so fun wa pe Opin Aye bu detan.
Ojo Nla Oluwa ku si dede, o ku si dede, O si i n yara kankan, ani ohun ojo Oluwa: alagbara Okunrin yoo sokun kikoro nibe, Ojo naa ojo ibinu ni. Sefinah 1:14-15a
Eyin pelu e mu suuru; e fi okan yin bale: nitori ipadawa Oluwa ku si dede. Jakobu 5:8
Ibeere: N je Ojo Iponju ati Idajo Olorun tile sunmo bi?
Idahun: Beeni, o ti sunmo pekipeki, Olorun ti funwa ni Oye re to ninu Bibeli, leyi to so fun wa pe Opin Aye yi ti sunmo tosi.
Ati nitori eSe yoo di pupo, ife opolopo yoo di tutu. Matteu 24:12,14
Nitori awon Eke kristi, ati eke wolii yoo dide, won o si fi ami ati ohun iyanu nla han; tobee bi o ba le Se-e-Se won yoo tan awon ayanfe paapaa. Matteu 24:24
Ibeere: Y = ato si ojo idajo ti yoo de,kini awon ohun ti yoo tun Sele lakoko Opin aye yii ?
Idahun: Awon wonni ti won ti gba JESU ni OLUWA ati ni Olugbala won, ni a o pa larada si ara Ogo ti Olorun,won yoo si maa wa pelu Kristi JESU OLUWA titi lae.
Nitori Oluwa tikarare yoo sokale lati orun wa ti Oun ti ariwo, pelu ohun Olori awon Angeli,ati pelu ipe Olorun; awon oku ninuu Kristi ni yoo si ko jinde. Nigba naa ni a o si gba awa ti o wa laaye ti o si ku leyin soke pelu won sinu awosanmo, lati pade Oluwa ni oju Orun: beeni awa o si maa wa titi lae lodo OLUWA. 1 Tessalonika 4:16-17
Bakanna ni Olorun yoo pa gbogbo Aye yi re pelu Ina, yoo si tun da Orun titun ati Aye tuntun miran, nibiti Jesu Oluwa yoo ti maa J = Oba pelu awon to ba gbaa gbo titi lae.
Sugbon ojo Oluwa n-bowa bi ole ni Oru; ninu eyi ti awon orun yoo koja lo ti awon ti ariwo nla, ati awon imole oju Orun yoo sii ti inu Ooru gbigbona gidigidi di yiyo,aye ati awon ISe ti o wa ninuu re yoo si jona luuluu. 11 Peteru 3:10,13
Ibeere: Kini eredi ti Olorun fi fun wa ni Ikilo yii?
Idahun: Gege bi Olorun ti Se 'kilo Saaju fun awon ara Nenefe igbaani, pe Oun yoo pa ilu Olokiki naa re ti o sii fun won ni ikilo Ogoji Ojo. Beeni Bibeli paapa kilo fun wa pe Opin Ohungbogbo sunmole tan.
Jona si bere si wo inu ilu naa lo ni irin Ojo kan, O si kede, o wi pe, Niwon Ogoji Ojo si i, a o bi Nenefe wo. Jona 3:4
Ibeere: kini ohun ti awon Ara Nenefe Se gidi?
Idahun: Lati Ori Oba titi deni to kere ju ni won re ara won sile niwaju Olorun Alaaye, won yipada kuro ninu Ese won, Won si ke rara sOke si Olorun fun Aanu.
Sugbon je ki eniyan ati eranko fi aSo ofo bora, ki won sii kigbe kikan si Olorun: si je ki won yipada, olukuluku kuro ni Ona ibi re, ati kuro ni iwa agbara ti o wa lowoo won. Jona 3 : 8-9
Ibeere: N je Olorun gbo Adura won bi?
Idahun: Beeni, Olorun fi aabo re bo Ogunlogo eniyan ni ilu Nenefe.
Ibeere: N je mo Si le ke pe Olorun fun Aanu, Ki n ma baa lo sinu Idajo Olorun?
Idahun: Dajudaju, A-Sii le wa igbala Okan wa bayi, sugbon ko kan fi bee si akoko ti a le fi Tafala mo ni, akoko naa kuru jojo.
E wa Oluwa nigba ti e le rii, e pe e, nigba ti o wa nitosi. Isaiah 55:6
Awa o ti se la a, bi awa ko ba naani iru igbala bi eyi; ti ateteko bere si i so lati Odo Oluwa, ti a si fi mule fun wa lati Odo awon eni ti o gbo; Heberu 2:3
Nipa Olorun ni igbala mi,ati Ogo mi: apata agbara mi, aabo mi si nbe ninu Olorun.Gbekele e nigba-gbogbo; eyin eniyan, tu okan yin jade niwaju re; Olorun aabo fun wa. Orin Dafidi 62:7-8